Ní nǹkan bí ọjọ́ méjì sẹ́yìn, mo ń ronú nípa ẹnì kan. Kì í ṣe lọ́nà kan pàtó, àmọ́ bí mo ṣe ń ronú nípa bí ẹni náà ṣe jẹ́ ẹni tẹ̀mí tó, ni Ẹ̀mí Mímọ́ bá mi sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́tù pé: "Ìgbé ayé tẹ̀mí ló ń gbé, kì í ṣe ìgbésí ayé Kristẹni". Ní àkókò yẹn, mo rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìgbésí ayé Kristẹni àti ìgbésí ayé tẹ̀mí.
Ọ̀pọ̀ nínú wa lè máà rí i pé ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan jẹ́ ẹni tẹ̀mí àmọ́ tí kì í ṣe Kristẹni. Ohun tí jíjẹ́ ẹni tẹ̀mí túmọ̀ sí ni pé kéèyàn máa lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò èyíkéyìí tó bá ní í ṣe pẹ̀lú wíwà ní ọ̀run. Ohun tí mo ń sọ ni àwọn ìgbésẹ̀ bíi gbígbàdúrà, sísọ àwọn ọ̀rọ̀ kan léraléra, ṣíṣe àṣàrò nípa tẹ̀mí, sísọ èdè tí kì í ṣe ti ènìyàn, ààwẹ̀ gbígbà, agbára láti bá àwọn ẹ̀mí rìn, kíkọrin àti àwọn mìíràn.
Ó ṣeé ṣe láti lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò wọ̀nyí láìjẹ́ pé a ti wẹ̀ ẹ́ mọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ Jésù, àti láìjẹ́ pé a tẹrí ba fún ìdarí àti ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, èyí sì jẹ́ díẹ̀ lára ohun tí jíjẹ́ Kristẹni túmọ̀ sí. Ìgbésí ayé Kristiẹni jẹ́ ìgbésí ayé ti ẹ̀mí nítorí ó ní àwọn ìgbésẹ̀ bí ìjọsìn, gbígbàdúrà nínú Ẹ̀mí Mímọ́, ààwẹ̀ àti àṣàrò, ṣùgbọ́n ìgbésí ayé Kristiẹni kìí ṣe ọ̀nà kan ṣoṣo sí ayé ti ẹ̀mí.
Nígbà tí ẹnì kan bá lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò tó lè jẹ́ kó dé ibi tí ẹ̀mí ń gbé, àmọ́ tí ẹ̀mí Ọlọ́run kò darí ìgbésí ayé rẹ̀ tàbí tí kò wà lábẹ́ ètùtù Jésù Kristi, ẹni náà jẹ́ ẹni tẹ̀mí àmọ́ kì í ṣe Kristẹni. Nígbà tí ẹnì kan bá ń gbàdúrà ní ahọ́n, tó ń kọrin, tó sì ń ṣàṣàrò, àmọ́ tí kò ní ìjẹ́mímọ́, ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, ìfòyemọ̀, ìfẹ́ láìní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ìkóra-ẹni-níjàánu àti ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bíi Kristi, tí kò sì fi hàn, ó ń fi hàn pé ẹni náà jẹ́ ẹni tẹ̀mí, àmọ́ kì í ṣe Kristẹni.
Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ máa lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí, irú bíi gbígbàdúrà àti ààwẹ̀ gbígbà, ṣùgbọ́n kì í ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí ló jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé Kristẹni. Ẹ̀dá èèyàn ti ní ìfẹ́ fún nǹkan tẹ̀mí tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi wà nínú gbogbo wa. A nílò Kristi láti mú wa wá sínú ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ lọ́nà tó yẹ. Jíjẹ́ ẹni tẹ̀mí kò sọ wá di Kristẹni rere, kàkà bẹ́ẹ̀, jíjẹ́ Kristẹni rere ni ọ̀nà láti mú kí ìgbésí ayé wa nípa tẹ̀mí jẹ́ èyí tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà, bá a ṣe ń gbé lábẹ́ ìdarí Jésù Kristi.
Ẹ̀mí Mímọ́ ní pàtó fẹ́ kí n fi èyí kún un gẹ́gẹ́ bí ìparí; ìgbésí ayé ẹ̀mí ni yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti borí àwọn ọ̀tá rẹ níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé kí o sì dé ibi-afẹ́ rẹ, ṣùgbọ́n ìgbésí ayé Kristiẹni ni yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rí Ọlọ́run ní ọ̀run.
Caleb Oladejo
Comments